2016/2017 NNL: FC Abuja fagba han FRSC FC

Tobi Sangotola/Ademola Adepoju.

0
122

Iko egbe agba-boolu FC Abuja fagba han egbe agba-boolu FRSC FC pelu omi ayo meji si ookan (2-1) ninu idije 2016/2017 torile-ede Naijiria (Nigeria National League:NNL).

Ifesewonse yii ni ikeji to waye laarin iko mejeeji, leyin ti iko egbe agba-boolu FRSC FC fagba han awon ti ilu Abuja ninu asekagba idije boolu torile-ede ohun (FA CUP), pelu boolu agbesile gba (penalty kicks) leyin omi meji-meji ti won gba papo ninu saa mejeeji ifesewonse yii (2-2), pelu omi ayo meji si merin(2-4), ti iko Abuja FC to wa fagba han awon naa pada ninu idije miran pelu ami ayo meji sookan(2-1) ni papa isere aarin gbungbun Area 3, ni ilu Abuja.

Muktar Saliu ti o je, agba-boolu FRSC FC lo gba ami akoko wole ninu ifesewonse ohun ki Gary Anyahmkeh ti egbe agba-boolu Abuja FC to da ami ayo naa pada, leyin ti Samaila Ishak agba-boolu fun ilu Abuja to gba ami miran wole ki saa akoko naa to ipari.

Akonimoogba David Emmanuel, fun egbe agba-boolu FRSC FC gboriyin fun awon agba-boolu re, ti o si so wi pe, won padanu ifesewonse naa nitoripe won ko lati gba boolu gege bi o se n dari won.

O tesiwaju, o ni: awon ni ami meje ninu ifesewonse mejo ti awon ti gba, ti awon si ti koja ami ti won nilo lati fi pegede fun ifesewonse miran, amo, awon yoo gbaradi daradara fun ifesewonse miran to n bo lona”.

Yunus El-Shama, akonimoogba iko egbe agba-boolu Abuja FC ti so wi pe, oun ti n reti esi ifesewonse naa tele lati fagba han iko FRSC FC nitori pe, awon agba-boolu oun ti mura gidigidi fun ifesewonse yii ko to waye.

O tesiwaju, o ni: inu mi dun pupo, mo dupe lowo Olorun fun esi ifesewonse ohun, mo gboriyin fun awon agba-boolu mi fun ise takuntakun ti won se. Gbigbaradi fun ifesewonse miran lo wa lokan wa bayi.

 

Tobi Sangotola/Ademola Adepoju.

 

LEAVE A REPLY