Aare Buhari ro awon obi lati mojuto eto eko awon omo

0
21
Buhari ki Osinbajo ku ise

Aare Mohammodu Buhari ti pe awon obi nija lati samojuto to ye fun eto eko awon omo won ki won le wulo fun awujo ni ojo iwaju. Aare pe ipe yii nile ijoba l’Abuja leyin to de lati ilu London to ti lo lo isinmi re.

O ni agbaye n fojoojumo yipada ni fun idi eyi, obi ati alagbato gbodo mura sile fun awon ogo weere to je ojo iwaju won ki won le ni imo to ye lori eto eko ati ipenija ojo ola.

Aare Buhari gboriyin fun awon onisegun oyinbo lori itoju to gba lasiko isinmi re pe ijoba Naijiria ko ni faaye gba ki awon eniyan maa loogun fun ra won lai gba imoran awon onisegun oyinbo.

Aare ni oun mo nipa isoro eto oro aje to n koju Naijiria. Bakan naa lo gboriyin fun fun igbakeji re, Ojogbon Yemi Osinbajo fun ise rere to se lati tuko orile ede yii nigba ti oun lo fun isinmi losu kinni odun. O ni awon yoo tubo jo maa sise papo lati mojuto isoro eto oro aje Naijiria.

SHARE

Fi èsì sílẹ̀