Aare orile ede Brazil Bo Lowo Ibo Iwadii lori iwa ibaje

Ademola Adepoju.

0
8999
Aare Michel Temer

Ile igbimo asofin orile ede Brazil ti yi ero okan won pada lati dibo ti yoo je ki won  se iwadii  aare Michel Temer lori iwa ibaje.

Awon egbe alatako nile igbimo asofin kekere kuna lati ni ida meji ninu ida meta nile igbimo asofin naa, lati le je ki won gbe ejo yii lo si ile-ejo giga ( supreme court).

Ogbeni Temer sapejuwo ibo yii gege bi”ohun ti ko ni aruloju ati eyi ti won ko le tako”

Won fi esun kan aare naa pe o gba owo riba  milionu mejila dola (£9m) lowo oga ile ise meatpacking , JBS.. Sugbon ti aare so pe iro ni.

“Pelu atileyin ti ile igbimo asofin kekere fun mi, a o se awon atunse ti orile ede yii fe”. Aare so eleyii leyin ibo ti won di.

 Aare tesiwaju pe” akoko niyi lati dokoowo ni orile ede wa.Orile ede Brazil ti setan lati tubo goke agba si i“.

O seleri lati lo akoko re tan, ni eyi ti yoo pari ni osu kejila odun 2018.

Eebu, odi oro siso ati ija, waye ni Ile igbimo asofin naa

 

Ademola Adepoju.

LEAVE A REPLY