Aare tuntun ile Faranse yoo se-abewo si awon omo-ogun lorile-ede Mali

Tobi Sangotola/ Ronke Osundiya

0
273

Aare tuntun fun orile-ede Faranse Ogbeni Emmanuel Macron, yoo se abewo si awon omo-ogun ti won se ise akanse ipetusaawo lorile-ede Mali lopin ose to n bo.

Orile-ede Faranse da si oro orile-ede Mali ni odun 2013, ni eyi ti won le awon omo-ogun olote iko al-Qaeda kuro ni ekun ariwa orile-ede naa ti won ti wa tele.

Orile-ede ohun ti ko awon omo-ogun ti iye won to egberun lona merin ti a mo si (Barkhane force) lo kaakiri ekun naa lati gbogun ti awon omo-ogun alakatakiti elesin islam, lara eyi ti a ti ri awon omo ogun egberun kan si orile-ede Mali.

Ogbeni Macron ni aare tuntun to dipo aare Francois Hollande ti egbe oselu Socialist.

Tobi/Ronke

LEAVE A REPLY