AARE YAHYA JAMMEH, TI ORILE-EDE GAMBIA TI TI ILE ISE IROYIN MIRAN PA

Abiodun Popoola, Abuja

0
25

Aare Yahya Jammeh, ti orile-ede Gambia ti ti ile ise iroyin Paradise FM ,ti yoo je ikerin re pa ni ose to koja, bi won se fiipa mu u lati fi ipo aare naa sile lataari bi o se fidi remi ninu eto idibo sipo aare orile-ede naa.
O ti ile ise iroyin naa pa lataari ase aare naa.
Titi ile ise naa pa waye leyin eto iforowanilenu wo pelu agbenuso apapo egbe kan ti o nse atileyin aare ti won dibo yan Adama Barrow, eyi ti Aare Yahya Jammeh ko lati gbe ipo fun leyin ti o jawe olubori ninu eto idibo naa to waye ni ojo kinni osu kejil;a odun ti o koja.
Awon ile ise iroyin eyi ti won ti pa tele ni Teranga FM, Hilltop FM ati Afri Radio. Eyi ti awon alase ile ise naa ko i ti so ohunkohun lori eyi.
Ajo awon akoroyin lorile-ede Gambia ti fi edun okan won han lori awon igbese naa, eyi ti o le sokunfa laasigbo oloselu lorile-ede naa.
Adama Barrow ti so wi pe oun yoo gba ipo naa ni ojo kokandinlogun osu kinni odun yi bi ofin orile-ede naa se fi lele, bi o ti le je pe Aare Yahya Jammeh ti gbe ejo naa lo si ile ejo

Fi èsì sílẹ̀