Aare Zuma pase ijiya to to je gbigbogun ti eto awon obirin

Abiodun Popoola

0
770
Aare orile-ede South Afrika Jacob Zuma

Aare Jacob Zuma ti pase fun awon agbofinro lati ma fi owo yepere mu iwa odaran tako eto awon odomobirin ati awon obirin lorile-ede South Afirika lokunkundun.

Aare Zuma so eyi di mimo lojo Wednesday OjoRu ni papa isere Galeshewe, ni ilu Kimberly lakoko ayeye ayajo awon obirin okanlelogota re lorile-ede naa.      

Aare so wipe, ko bojumu lati fi owo yepere mu awon ti won ba n fi eto awon obirin gbole tabi fi iya je won lona aito.iru eniyan to wu ki won je lawujo won gbodo foju ba ile ejo.

Aare orile-ede South Afrika so wipe ijoba orile-ede naa yoo tesiwaju lati ma mu oro awon obirin lokunkundun,ti o si nipa opolopo awon iranlowo ati anfaani ,ti won ti se fun awon obirin ati omode.

O wa gboriyin fun awon obirin ti won lami laaka lawujo,ti won gbogun ti eleyameya lojo kesan osu kejo odun 1956.

Minisita fun idagbasoke awujo lorile-ede naa, Bathabile Dlamini  fi anfaani ayeye naa lati gboriyin fun Aare Zuma ,leyin ti ori koyo ninu eto idibo mi mo okan ara ilu.

Eni ti o je adari awon obirin ninu egbe oselu ANC koju awon ti won n gbiyan lati yo Aare naa nipo ninu ile igbimo asofin lojo isegun Tuesday.

O tesiwaju ninu oro re wi pe ,awon ota yi lo ogbon arekereke won lati igba pipe,won faramo gbigba ipo pelu ipa,dipo eto idibo,nitori wipe won yo fidi remi ninu eto idibo.

Minisita naa wa pe awon okunrin kaakiri eka gbogbo lorile-ede naa,ninu eyi ti awon omo egbe oselu ANC wa lara won,lati fi idunnu won han lori gbigbogun ti fifiya je awon obirin.

 

Abiodun Popoola

LEAVE A REPLY