Abuja, olu-ilu Naijiria ati agbegbe re san gbese awon agbasese

0
352

Owo to to le ni bilionu metadinlogota owo naira ni won san fun awon agbasese lori awon ise akanse ti won se lorisiirisi nilu Abuja ati agbegbe re. Ijoba ekun yii san gbese naa fun ise akanse ipese omi, oju ona, oju oko reluwe, ilera, eto eko ati ise awon agbale.

Minista fun FCT, Muhammed Bello, eni ti Ogbeni Isiaku Ismaila, to je oludari ibi owo to dabi akapo soju fun ba awon oniroyin soro pe igbese yii wa niba mu pelu erongba ijoba lati pese awon ohun amayederun gbogbo fawon ara ilu. O ni:

“Awon agbasese to je eniyan orile ede yii tijoba je lowo to din logorun un milionu naira ni won ti san gbese won fun. Igbese sisanwo yii je eyi ti a je ko han kedere si awon eniyan. Gbogbo awon to bo si abe isori yii je awon metadinlogbon le ni egbeta ni eyi ti owo won ti to lati san gege bi o se wa ninu iwe isuna todun 2016. Yato si owo bilionu meta le nida meta ti won san nibere odun yii fawon towo won ko po to ogorun un milionu. Inu mi dun lati so pe gbese wa n dinku gidi lati odun 2016 titi di isinyii ni eyi to le nida aadota ninu ogorun un.“

O ni itoju oju popo ati agbegbe je ijoba to wa lori aleefa bayii logun. Bakan naa lo salaye pe ijoba ti sanwo lori ilera fawon osise won fun adojutofo won ti won si ti san owo to ye ti won je awon osise feyinti tele. O ni milionu meji ati ida meta ni won ti fi san gbese ajemonu fawon osise feyinti.

“Bakan naa nijoba FCT ti fe satunse ipese ounje ofe fawon akekoo ni eyi ti yoo gba to okoo din ni bilionu owo naira kan fawon ile iwe to wa labe akoso FCT.”

Minista ni ijoba FCT ti fi bilionu meje kale fun awon agbasese to n sise lori oko irinna oju irin ni Abuja kise le bere lori abala akoko ki o le see lo titi osu kinni odun 2018.

O soro lori ise akanse ijoba lori ipese omi to mo gaara fawon olugbe ekun naa lasiko. Ni afikun, o menuba ajosepo to dan moran to wa laarin ijoba FCT atawon ijoba ibile abe won ni eyi ti o ti gbe gbogbo owo to ye kale sinu asunwon awon ijoba ibile ti won ni papo.

Ni ipari, o nijoba ko je awon oluko ni gbese kankan nitori owo osu won n lo deedee.

LEAVE A REPLY