Afrobasket: D’Tigress yoo maa gbera lo si orile-ede Mali lose to n bo.

Tobi Sangotola.

0
197
DTIGRESS

Sam Ahmedu, ti o je okan gbogi lara egbe to n ri si ere idaraya boolu afowogba lorile-ede Naijiria (NBF), ti so pe iko D’Tigress ti orile-ede Naijiria, yoo maa gbera losi ilu Bamako, lorile-ede Mali lojo kerindinlogun inu osu ti a wa yii, lati lo kopa ninu idije boolu afowogba ti awon obinrin to n bo lona.

Beeni, idije ohun yoo bere lojo kejidinlogun inu osu ti a wa yii.

Ahmedu fikun oro re pe. “ipese ti o wa nile bayii ni o wa fun awon iko naa lati ririn-ajo lo si ilu Bamako, lorile-ede Mali lojo kerindinlogun inu osu yii, bakan naa ni eto ti wa nile ni sepe. 

Ahmedu tesiwaju pe,” iko D’Tigress yoo tun lo fun ifigagbaga olorejore keji pelu iko Raptors lojobo(Thursday).

Ninu ifigagbaga akoko pelu iko Raptors lojoru(Wednesday), D’Tigress padanu ifigagbaga ohun pelu ami mokanlelaadorin  si ami marundinlogota (71-55).

“o dara wi pe iko D’Tigress padanu ifigagbaga akoko ohun, eyi yoo mu ki awon akonimogba won tun bo te pa mose si, ati lati mu atunse ba awon  kudie-kudie won.”

 

Tobi Sangotola.

LEAVE A REPLY