Aisha Buhari sayewo fawon asatipo

0
545

Iyawo Aare orile-ede Naijiria, abileko Aisha Buhari tepele mo Pataki ki awon obinrin maa sayewo ago ara won ki won le maa gbe igbe aye alaafia. Abileko Buhari  so eyi lasiko ti won sayewo fawon eniyan ni Durumi nibudo awon asatipo lÁbuja.

 “Mo n ro awon obinrin lati mojuto ara won loorekoore. Ki won maa sayewo ito won, ifunpa won, eje won ati beebee lo. Ki won maa sayewo arun iba, aisan eja, ayewo oyan ati oju ara won fun arun jejere. O ni nipa sise ayewo yii ni won yoo le fi gbe igbe aye alaafia.”

 Asoju alamojuto ajo ise ti kii se tijoba, Onisegun oyinbo Kamal Abdulrahman, lo soju iyawo Aare nibi eto naa, eyi ti won pe ni idaniloju ojo iwaju rere. Ajo idaniloju ojo iwaju rere yii ti seto ayewo naa nibudo marun un kaakiri ekun kookan lorile ede Naijiria.

Aya Buhari ni ise si n lo lati lo si awon igberiko ninu awon ekun kookan ni ekun mefeefa kaakiri orile ede yii.

Ajosepo

Won n se ayewo yen pelu ajosepo ajo Cry for Help Foundation. Onisegun oyinbo Alfred Sanni, to je akowe  agba ajo naa gboriyin fun aya Aare Buhari fun igbese akoni naa. Won sayewo fawon omo won lori eti, imu, ati ona ofun.

Abileko Buhari tun pin ounje, aso, ose ati nnkan eelo lorisiirisi fawon asatipo.

 

LEAVE A REPLY