Ajo FIFA yan Adajo Naijiria kan si igbimo Omoluwabi

0
160
FIFA yan Adajo Ayotunde sipo

Ajo adari isele inu ere boolu alafesegba lagbaye (FIFA) ti yan Adajo agba fun ipinle Eko, Adajo Ayotunde Phillips, gege bi okan lara omo igbimo iwa Omoluwabi ninu ajo naa lojo Bo.

Eyi je iroyin rere fun awon ololufe ere boolu nile Adulawo ati fun eniyan orile-ede Naijiria nitori pe oun ni Adajo akoko ti won yoo yan siru ipo bee. Adajo yii ni alaga ajo eleto idibo fun ipinle Eko lowolowo.

Won yan Adajo naa nibi ipade gbogboogbo ajo FIFA to wa ye ni Manama ni Bahrain eyi to je iketadinlaadorin iru re. Eyi tun je eri miran pe orile–ede Naijiria ti n goke agba ninu ajo ere boolu lagbaye pelu yiyan ti won yan aare NFF sipo ni CAF ati ni FIFA bayii.

Vassilios Skouris lati Greece ni alaga Igbimo Omoluwabi tuntun fun ajo FIFA bayii, igbakeji re ni Fiti Sunia (American Samoa), eni to je adajo nigbakan ri.

Awon omo igbimo to ku ni: Mohammad Ali Al Kamali (United Arab Emirates: Asia); Aivar Pohlak (Estonia: Europe); Margarita Echeverria (Costa Rica: North ati Central America ati the Caribbeans); Jack Kariko (Papua New Guinea: Oceania); pelu Flavio Zveiter (Brazil: South America).

LEAVE A REPLY