Ajo NCC ri to eniyan aadorun milionu to n lo ayelujara losu kerin odun yii.

0
963

Ajo to n mojuto ona ibanisoro ni Naijiria ti a mo si “The Nigerian Communications Commission” (NCC) ti ni pe o to eniyan milionu lona aadorun to lo ayelujara losu kerin odun yii.

Ajo NCC ni igbese ayewo olosoosu ti won se nipinle Eko lo fi eleyii han. Iwadi yii fihan pe odinwon iye awon to n lo data ni ti GSM ati CDMAni osu kerin le to iwon egberun lona ogorun si awon to loo ni osu keta. Eyi fihan pe o le ni egberun mokanlelaadojo awon eniyan to safikun le awon to n loo tele losu kerin yii.

Awon CDMa ri to eniyan egberun lona ogbon sii losu kerin yato si tosu keta. Iwadii yii fihan pe awon to n lo MTN le ni egbelegbe lona igba losu naa ni eyi ti Globacom din legbelegbe metadinlogbon ati beebee lo.

Airtel ni to egbelegbe lona mokandinlogun losu keta nigba ti Etisalat ni o le ni mejila ero losu kerin eyi to fihan pe o din sawon to n loo losu keta to le ni egbelegbe metala.

Iwadii naa fihan pe ti Visafone ati Multi-links ri bakan naa pelu tosu keta eyi to je o le die legberun lona ogbon. Iwadii naa tun fihan pe awon merin pere lo n fi Multi links sise lori ero ayelujara nigba ti o le ni egberun lona ogbon n lo Visa fone.

O fihan pe alekun de ba odiwon awon to n lo ayelujara ni Naijiiria losu kerin odun yii ni eyi to wa nibamu pelu erongba ida ogbon ninu ogorun titi odun 2018 ti won ni lokan.

LEAVE A REPLY