Amaju Pinnick gba ipo labe ajo to n ri si boolu afesegba ni ile Afrika

Tobi Sangotola ati Ademola Adepoju

0
350

Aare egbe agba-boolu fun orile-ede Naijiria (NFF), Amaju Pinnick, lo ti di aare tuntun ti won sese dibo yan fun boolu alafesegba ni ile Afrika (AFCON), ati omo egbe tuntun fun ajo to n ri si boolu awon alawodudu (CAF).

Ipo tuntun yii ni won fun un nibi ipade ti o waye laarin awon akegbe re ti o je asoju fun ile Afrika  nipa boolu afesegba ni ilu Manama, lorile ede Bahrain.

Eyi ni ipade akoko ti o waye lati ojo kerindinlogun osu keta odun yii ti won dibo yan Ogbeni Ahmad Ahmad, fun aare egbe tuntun to n ri si boolu afesegba ni ile Afrika, leyii ti won si dibo yan Pinnick naa fun omo egbe tuntun sinu ajo yii.

Awon ise akanse marundinlogun lorisirisii ni ajo yii ti ko kale lati gbese lasiko saa odun merin ti won yoo lo lori oye gege bi asoju egbe ohun, leyii ti egbe ohun yoo si dari latowo aare tuntun Ahmad.

LEAVE A REPLY