Arsenal fagba han Chelsea lati gba ife eye Community Shield

Tobi Sangotola.

0
157
Arsenal FC

Atamatase iko agba-boolu Chelsea Alvaro Morata, padanu boolu agbesile gba ninu ifesewonse ife eye Community Shield,  ti o waye ni papa isere Wembley, ni ilu London.

Iko agba-boolu Chelsea gba ami ayo akoko wole, eyi ti o waye lati owo Victor Moses, kio to di wi pe adari ifesewonse ohun le Pedro agba-boolu iko Chelsea jade lataari asemase re ti o se ninu ifigagbaga pelu Mohamed Elneny.

Agba-boolu tuntun iko Arsenal, Sead Kolasinac lo fori da ami ayo ohun pada, ti saa ifesewonse mejeeji si pari si ami ayo kookan, leyi ti o sun ifesewonse naa lo si agbami boolu agbesile gba(Penalty kicks).

Boolu agbesile gba ohun ni won gba pelu ilana tuntun ti ajo fifa sese gbe kale ilana(ABBA), ti o tunmo si pe agbaboolu iko akoko yoo gba, ti iko keji yoo si gba tele ra won.

Balogun iko agba-boolu Chelsea, Gary Cahill  lo bere boolu agbesile gba ohun, ti o si gba wole. Kii Theo Walcott, Monreal ti won je agba-boolu iko Arsenal o to gba ti won naa,

Amule iko Chelsea Courtois, padanu boolu ti e, beeni Alvaro Morata naa padanu. kii Alex Oxlade Chamberlain ati Olivier Giroud  o to gba boolu ti won wole, ti ifesewonse naa si pari si ami ayo merin sookan(4-1).

 

Tobi Sangotola.

LEAVE A REPLY