Àwo̩n As̩ojú-s̩òfin Nàìjíríà ní Olùdarí È̩s̩ó̩ e̩nubodè gbò̩dò fojúhan ilé

0
17

Àwon o̩mo̩ ilé ìgbìmo̩ As̩òfin ní Nàìjíríà ti fi dandan sii pe Olùdarí ajò̩ è̩s̩ó̩ e̩nu bodè Naijiria, Ò̩gbé̩ni Hammed Ali, gbo̩dò̩ fojúhàn ló̩jó̩ ‘Ru láti wá yànàná ìlànà tuntun to rò̩ mó̩ owó orí lori awon oko to n wole.
Àwo̩n as̩òfin fenuko pe o gbodo yoju sile leyin ipade won lojo isegun to koja leyin ti Ogbeni Hammed Ali ti ni ki won fun oun ni aaye díe̩ sii.
Awon omo ile ko gbe ebe re wole lataari pe oun gangan ko lo fowosi leta to ko ranse ni eyi ti awon omo ile ka si arinfin. Ninu leta naa ti ile akede Naijriria ni eda re ni pe ojo ti ile igbimo ni ki Hammed yoju si won tun bo si ojo to ni ipade Pataki pelu awon oludari eso enubode. Eyi lo mu ki o beere fun ojo miran lati wa salaye lori koko naa.
Azarema to je igbakeji oludari agba ajo eso enu bode Naijiria lo bowo lu leta naa fun oga re.
Awon Asoju-sofin ri ihuwasi re gege bi arinfin nitoripe idi to fi siele ko moyanlori to loju ti won. Fun idi eyi, won fun un laaye lati yoju sile ni ojo’Bo to n bo ni eyi ti o ye ko rorun fun un lati wa.
Asofin James Manager to je enikeji to soro lori leta naa ni ile ko gba ihuwasi oludari ajo enubode wole rara. Ati pe o gbodo yoju sile pelu aso ise re ni ki ohun gbogbo le yanju lola.
Bakan naa ni Saraki ni ile yoo wo adele adari ajo to n gbogun ti iwa odaran ni Naijiria ti amo si EFCC wo lola ki won sim o boya o ye fun ipo oludari.
Ile gba abadofin lati satunse si ilana ofin owo adojutofo fun awon osise gege bi todun 2010 se laa kale.
Abadofin fun isafihan to ye ninu eka isakoso naa ni ile tun ka wole leekeji ninu ipade naa ni ey ti yoo je ki awon adari safihan awon ona owo nina ati owo ori sisan fun awon to ye.
Ni ipari, ile tun ka abadofin fun sise agbekale ajo ti yoo ma samojuto awon arun ni Naijiria ati ona idena re leekeji.

SHARE

Fi èsì sílẹ̀