Awon agbebon lo sile igbakeji Aare ile Kenya

0
141

Awon agbebon kan ti enikeni ko damo ti kolu ile William Ruto to je igbakeji Aare ile Kenya ni ekun Uasin Gishu. Iroyin ni awon agbebon naa segun awon olopaa to wa lenu ona ile naa ki won to raaye wole.

Isele yii waye lasiko ti Ogbeni Ruto ko si nile lataari pe o ti lo sibi ipolongo nilu Kitale nibi to ti lo pade Aare Uhuru Kenyatta ni eyi to bo si o ku ojo mewaa ki eto idibo fun ipo aare ati awon asoju fi waye ni Kenya.

Ogbeni Kenyatta n tun apoti gbe leekeji fun ipo aare ninu idibo to m bo losu to m bo. Eto idibo ile Kenya fun odun 2013 lo niroworose sugbon todun 2007 bige ati adubi to ja si iku fawon eniyan to le legberun kan ti awon to le ni eedegbeta padanu ile ati dukia won.

Bayii, awon akosemose n woye pe won ko lero ikolu ti yoo to bee yen mo ninu eto idibo ti yoo waye lojo kejo osu kejo odun yii ni Kenya.

 

 

 

LEAVE A REPLY