Awon asoju-sofin ni ki ise oko-oju-irin kari ekun kookan

0
597

Awon asofin agba lorile-ede Naijiria ti fi dandan sii pe ki ise to n lo lowo lori ipese oko-oju-irin lorile–ede yii wa kaakiri ekun kookan ni. Won ni ki awon to n sise naa tele ilana agbekale to wa ni eyi ti won koko ya nibi ti oko-oju-irin ti wa kaakiri Naijiria gege bii oko irinna.

Onisegun oyinbo Bukola Saraki to je aare ile ni ise yii ko gbodo yo ekun Kankan sile rara. Asofin Enyinnaya Abaribe,okan ninu awon omo ile lo side oro lori koko yii ninu ipade won. O ni bi won se yo ekun guusu kuro ninu ise akanse fun todun 2016 si 2018 naa ku die kaa to. O ni owo ya tijoba n beere fun lati fi sise naa ko wa fun ekun iwo oorun nikan.

Abaribe pe akiyesi ile si oro naa pe sise oko oju irinna ni ekun yii yoo je ki irinna rorun lati guusu orile-ede yii si ariwa ati si iwo oorun.

Saraki fi da a loju pe ise irinna oko-oju – irin yoo kari Naijiria. O ni  “A maa gbe oro yii lo soke gege bi o se ye pelu awon igbimo amusese, eyi lo mu iyato die de ba leta Aare. Leta aare akoko ko soro lori ise ni ekun guusu ila oorun si ariwa ila oorun. A ti fi ye aare pe ise akanse gbodo kari ekun kookan ni. Mo ro pe ohun to se Pataki ni pe ka rii pe igbese inu leta aare di mimuse ki a ma se soro lori eleyameya mo.

Olugbenga Ashafa, to je alaga igbimo eto irinna nile naa safikun soro Saraki pe ise irinna naa de Onitsha si Aba; ilu meji to kun fun karakata julo ni ekun guusu ila oorun Naijiria. O ni “o digba tise naa ba pari ki oye ise akanse nla naa to ye gbogbo eniyan”

Abaribe ni nigba to je pe gbogbo ekun ni yoo kopa ninu sisan owo ya naa, o dara ki ise naa kari ekun kookan. O woye pe awon ilu kan jasi ekun merin ni Naijiria bii guusu-guusu si guusu ila oorun si aarin gbungbun ariwa si ila oorun ariwa. Awon ilu naa ni Port Harcourt, Aba, Enugu, Makurdi, Lafia, Gudi, Jos, Bauchi, ati Maiduguri.

Ni ipari awon omo ile fenuko lati pe minista fun eto irinna ni Naijiria lati wa salaye idi ti won fi yo guusu kuro ninu ise akanse eyi ti won fe lo owo tijoba ba ya lowo banki Exim ni China fun

Won ko fenuko si pe kile ma tii fowo si yiya owo naa laije pe awon toro kan se atunse bi o ti ye si eto irinna oju irin naa. Lojo kerindinlogbon, osu kerin odun nijoba apapo gbe oro owo yiya lati China naa wa siwaju ile $5,851 bilionu owo dola ni won fe ya  lati China Exim Bank ki won le rii fi se abala ti ipinle Eko-Kano, Kano-Kaduna, Eko-Ibadan, ati Eko-Calabar.

 

LEAVE A REPLY