Awon Oloogun Seku-pa Awon Omo-ogun Olote ni Ilu Borno

Ronke Osundiya.

0
408
Awon omo-ogun orile-ede Naijiria seku pa awon omo-ogun olote

Awon omo-ogun orile-ede Naijiria seku-pa awon omo-ogun olote mefa ni agbegbe ijoba ibile Dikwa nipinle Borno lasiko akanse ise ituka awon omo-ogun olote to ku ni ipinle naa.

Alukoro fun ile-ise oloogun naa, ogagun-agba Sani Usman fi mule ninu atejade kan nilu Maiduguri lojo-Ru(Wednesday) pe, awon omo-ogun seku pa awon olote naa lojo-aje (Monday)

 “Awon omo-ogun iko keje, ekun Dikwa ti won n sise akanse ALAAFIA TIPA-TIPA pelu ajosepo awom omo-ogun kanpa ibile, (civilian Joint Task Force) CJTF)ni won fara-sinko seku-pa awon olote naa laarin  agbegbe abule Bulabirin ati Mongole”.

Lasiko ikolu naa, awon oloogun seku-pa awon olote mefa nigba ti awon yoku farapa yan-na-yan-na.

.Ogagun Usman so pe, awon omo-ogun ijoba ohun gba okada mefa, ibon meta, ada kan lowo awon omo-ogun olote naa

Bakan-naa ni o tenumo pe, ojuse ati akitiyan awon omo-ogun orile-ede Naijiria ni lati sigun mo awon alaironu-piwada omo-ogun olote Boko haram kuro lorile-ede Naijiria pata pata.

 

Ronke Osundiya.

LEAVE A REPLY