Awon oluko lorile-ede Naijiria ti won to millionu lona meji loti foruko sile pelu ajo TRCN

Abiodun Popoola.

0
208
TRCN

Awon oluko ile eko jeleosimi, alakobere ati girama ,eyi ti o to millionu meji ni o ti foruko sile gege bi awon oluko to danto , ti won si mo ojuse won ni won labe ajo to nse amojuto awon oluko to danto, ti won si je akosemose ti a mo si Teachers Registration Council of Nigeria, (TRCN)

Oga agba ati alamojuto ajo naa, Ojogbon Josiah Oluwasegun Ajiboye, ni o so eyi di mimo lakoko abewo re si ile akede Naijiria Voice of Nigeria ni ilu Abuja .

Ojogbon Josiah Oluwasegun Ajiboye, so wi pe pelu ifowosowopo egbe to nrisi ayedaade awon oluko lorile-ede Naijiria, ajo naa ti pin awon iwe eyi ti awon oluko naa yo lo lati so nipa won ati ise ti won se ni awon ijoba ibile gbogbo lorile-ede Naijiria.

 “Eyi yo mu rorun fun wa lati mo iye oluko ti a ni,ati ibi ti won fidi kale si,yoo si tun gbegidina pinpin awon oluko si ona ati agbegbe ti ko to.”

Lara awon aseyori eyi ti o ti waye ni, sise idanimoran awon akosemose oluko, o le ni egberun lona meedogun ti yo joko fun idanwo yi ni gbogbo ipinle ati olu ilu orile-ede Naijiria, ati opolopo awon oluko ti won kose mose ni won ti foruko sile,

Fifun awon oluko ti won danto ni iwe ase lati gba ise ni ile okeere.

Gege bi oro re, iwe idanimo ati bi awon oluko se danto lenu ise, ni awon ile-iwe awon oluko lorile-ede Canada, Australia, Britiko ati Amerika ti o to meerinlelogun.Eyi yo fagile idanwo eyi ti awon oluko ma joko fun ki won to gba won senu ise  ni ile okeere.

O se alaaye wi pe,eto idanimo ati amojuto je eyi ti won yo mu lokunkundun lodun 2018 lati gba awon ayederu oluko danu.

Eyi yo si wa ye ni awon ile eko aladani ati ti ijoba.Akoko ati igba sise amulo awon oluko ti ko koju osuwon to ti dopin,

Ojogbon Ajiboye so wi pe ,ajo yi ti se to ibura ni awon ile eko  awon oluko mokanlelogbon kaakiri ipinle metadinlogun, nigba ti awon oluko ti won to egberun lona ogbon si ti gba iwe eri won.

 

Abiodun Popoola.

 

LEAVE A REPLY