Awon omo ogun ile Naijiria ti mu afurasi ajinigbe, agbesunmomi.

0
267

Awon omo ogun ile lorile-ede Naijiria, iko Forward Operation Base, ni Fika, ti mu afurasi onise ibi Boko haram kan ti oruko re n je Bala Ibrahim to je omo ogbon odun ni Fika. Afurasi yii je omo bibi abule Bulabulin nijoba ibile Fika, nipinle Yobe.

Awon omo ogun iko Forward Operation Base Yuga ti dena de awon onise ibi ti owo won si ti te awon afurasi ajinigbe merin ni abule Mundu. Awon omo ogun gbe igbese yii lataari ifitonileti awon ara ilu to n fere fun rawon.

Oruko awon afurasi naa ni Yahaya Auta, omo odun meedogbon; Salisu Lawal, omo ogun odun; Umar Mohammed, omo odun mejidinlogun; ati Samaila Abubakar. Won ba ibon agbelero nla kan, ota ibon, ada meji, obe kan, ero ibanisoro alagbeka meji, paali oogun tramol meji, ati ogota naira le loodunrun lowo won

Iwadii n lo lowo lori awon afurasi naa.

LEAVE A REPLY