Awon omo ogun ile ri o le nigba eniyan gba lowo Boko Haram

0
16

Awon omo ogun ile iko kejilelogun ti Garrisin, to je ti Lafiya Doole pelu awon ara ilu to n bawon gbogun ti awon onise ibi Boko Haram to je JTF ti ri eniyan mokanlalenigba gba ni abule Murye ati Mala nipinle borno, lapa ariwa ila oorun Naijiria.

Bakan naa ni awon omo ogun ri keke mokanla gba ti won ti fi oko akeru mejidinlogun ko awon ounje awon asatipo kuro ni Mala Maja.

Opolopo ise ni awon omo ogun ti n se lati safomo apa oke oya ile Naijiria ti won si n le awon onise ibi boko haram ati awon ajerangbe atawon odaran miran kuro nibi kolofin won gbogbo.

Ogagun Sanni Kukasheka Usman to je alukoro fawon omo ogun ni “lori eyi ni awon omo ogun ti sise lo si agbegbe Gombi, Guriki, ati Bobini nipinle Adamawa ati eya mii nipinle Borno. Awon ti a pin si Garkida si n dina lapa Jau ki won le sawari awon boko haram to ba wa nibe. Abule Wurolade ati ekun to paala pelu orile ede Cameroon naa nise si n lo titi de Mararraba Pella, Kalla, Shangui ati Opopona Hong-Garaha.”

Bakan naa ni won ti le awon boko haram ni abule Ajigin ati Talaba. Won ri ado oloro meji ti a we ni Ummarari  lana eyi ti awon iko to m ba ado oloro je ninu awon olopaa sise le lori.

O ni lojo abameta to koja ni awon agbesunmomi meji lobinrin gbiyanju lati wo Maiduguri lati Ummarari. Omo ogun ile yinbon pa okan ti ekeji si ju ado oloro naa lu ara re niberu. Awon mejeeji nikan lo farapa ninu isele naa

SHARE

Fi èsì sílẹ̀