Awon omo-ogun olote Islam so pe, awon ni won wa nidii ikolu to waye niluu Kabul

Ronke Osundiya.

0
342

Iko alakatakiti elesin Islam so lojo-aje Monday pe, awon ni won wa nidii ikolu kan to waye ni ilu ile-ise orile-ede Iraq to wa ni ilu Kabul lorile-ede Afghanistan, eyi ti o bere pelu ikolu ifemi ara-eni sofo ni enu-ona,  ti o si fun awon agbebon laye lati wo inu ile naa lo, ti won si fija peeta pelu awon eso eleto-abo.

Isele yii waye leyin ose kan ti awon eniyan marundin-logooji padanu-emi won ninu ikolu kan ti awon omo-ogun olote Taliban fi kolu awon osise ijoba ni ilu Kabul, ni eyi ti won bori awon  omo-ogun eleto-abo orile-ede Afghanista, ni ekun ti ilana orile-ede ti fidi mule.

Awon omo-ogun eleto-abo orile-ede Afgan fija peeta pelu awon agbebon fun opolopo wakati, ki minisita fun oro abele to kede ni osan ojo naa pe, ikolu ti o n lo lowo ni agbegbe ti won ti n ta, ti won n ra ni olu ilu ohun ti wale.

 

Ronke Osundiya.

LEAVE A REPLY