Awon omo ogun ori ile Naijiria ri omobinrin Chibok kan sii

0
20

Awon omo ogun ile Naijiria ti won je “Lafiya Doole” tun ti sawari omobinrin Chibok miran, eni to je okan lara awon akekobinrin ti awon Boko Harram ji gbe tele. Oruko re ni Rukayat Abubakar, eni to ti di abiyamo pelu omo osu mefa lowo re bayii.
Awon omo ogun ile Naijiria ri Rukaya lasiko ti won n fo ile awon onise ibi Boko Harram. Omodebinrin yii je omo bibi Abubakar Gali Mulima ati Habiba Abubakar ti agbegbe Chibok ni ipinle Borno ni apa ariwa ila oorun Naijiria.
Baba Rukaya ni o je omo ile iwe Chibok School to wa ni kilaasi 3B ti ipele keta eto eko ipele agba nile iwe girama ki won to jii gbe lojo kerinla osu kerin odun 2014.
Bayii, Rukaya wa nile iwosan nibi to ti n gba itoju ni kete ti o ba gba itoju to ye ni ijoba yoo faa le ijoba ipinle Borno lowo.

Fi èsì sílẹ̀