Benitez: Mo n sise lo ni Newscastle bii akonimoogba won

Tobi Sangotola/Ademola Adepoju

0
112

Akonimoogba ti iko egbe agba-boolu Newcastle, Rafael Benitez ti setan lati tesiwaju gege bi akonimoogba egbe agba-boolu Newcastle, leyin idaniloju tori gba lati owo eni to ni iko egbe yi, Ogbeni Mike Ashley, wi pe oun ti setan lati ra awon agba-boolu to danto ti akonimoogba naa ni lokan lati ra wa sinu iko egbe naa, lataari ipegede sinu idije boolu to gbayi julo ni orile-ede England.

Mike tesiwaju, o ni inu oun dun lopolopo lataari pipegede sinu idije boolu to gbayi julo ni orile-ede England, leyi ti o mu owo to po wa. Iyen milionu lona aadosan owo ile okeere, ti o wole sinu asuwon iko egbe agba-boolu naa

Ogbeni Mike Ashley, si fi da akonimogba Rafael Benitez loju pe, gbogbo awon agba-boolu to ni lokan ni awon yoo sapa won lati ra wa sinu iko egbe yii. Akonimogba Rafael Benitez, fi inu didun re han fun aseyori iko egbe agba-boolu yii ninu ipade ti o waye laarin awon oludasile iko egbe agba-boolu naa lati mu gbogbo erongba re wa si imuse ninu idije to n bo lona.

Rafael tesiwaju, A ti setan lati gbaradi fun idije boolu to n bo lona, lowo awon ololufe egbe agba-boolu yii fun aduroti won ni gbogbo igba, a n fi da won loju pe iko egbe agba-boolu naa ko ni jawon kule ninu idije ohun.

Tobi Sangotola/Ademola Adepoju

LEAVE A REPLY