Bisoobu-agba ni Naijiria di aare Lutheran ni agbaye

0
226
Won ti yan Alufa Musa Panti Filibus, to je Bisoobu agba fun ijo Lutheran Church of Christ ni Naijiria (LCCN), gege bii aare ijo naa Lutheran World Federation, (LWF) ni agbaye.
Won yan bisoobu yii nipade eleekejila ijo naa to waye ni Windhoek, ni Namibia, lojo Abameta, ojo ketala osu karun un odun yii.

Omowe Filibus ni eni ketala ti yoo dipo naa mu to je ara ile Adulawo keji lati odun 1947 tijo naa ti bere. O jawe olubori ninu eto idibo to waye nibi to ti ni ibo merinlelaadorin o le nigba laarin ibo meta le loodunrun to waye.

Omowe Filibus lasiko to n soro iside leyin to di aare ni ohun yoo mojuto ajosepo laarin awon eniyan, oro awon odo, ihinrere titankale kaakiri, ajosepo awon onigbagbo ati awon elesin miran ati bee bee lo fun idagbasoke alaafia ati idajo.

O se Pataki ki ajosepo to dan monran wa. Eyi je ebun fun omo eniyan. O dara ki a gbe igbese sidagbasoke Alaafia, ife ati idajo ni eyi ti onikaluku yoo jiyin le lori”

Alufa Filibus, ti sise seyin lorisiirisii. Oun naa wa lara awon to dide ki won to yan alufa akoko lobinrin fun LCCN lodun 1996. O seleri lati rii pe ijo sa ipa won fun idagbasoke awon odo. Bakan naa lo ro awon odo ati ewe lati satunse to ye sirin won.

Oun ati iyawo re, Alufaa Ruth filibus, bi omo meta ti won ti dagba. Oun ni yoo gba ise lowo Bisoobu Munib A.Younan to wa lati eka ijo naa ni Jordan eni ti won yan losu keje odun 2010. Omo ile Adulawo akoko ti yoo dipo aare mu ni bisoobu Josiah Kibira lati eka ijo naa ni Tanzania to sise lodun 1977 si 1984.

LEAVE A REPLY