Buhari seleri lati pese ilera to peye fawon eniyan

0
22
Buhari si ibudo ilera ni Kuchingoro

Aare Mohamodu Buhari ti fi da gbogbo eniyan Naijira loju pe ijoba apapo yoo pese ilera kariaye fawon eniyan orile ede yii. Aare soro yii nibi iside ibudo ilera abele ti kariaye ni Kuchingoro nilu Abuja to je olu ilu Naijiria.

Buhari fi ireti han pe ijoba oun yoo mu ileri pipese eto ilera to ye se pe”Mo ni ireti pea won obinrin wa ko nii ku lasiko ibimo mo, awon omo wa ko ni ku lainidi mo ni rewerewe lataari airowo san nile iwosan. Mo fe fi da awon eniyan Naijiria loju pe ijoba yoo sa ipa re lati pese eto ilera kariaye fun gbogbo eniyan Naijiria gege bi won se laa kale ninu ilana ofin ilera todun 2014. Bakan naa ni mo fi n da awon eniyan loju pe ijoba mi yoo mu gbogbo ileri ti a se se laipe”.

Aare ni sisi ibudo eto ilera alabele ti Kuchingoro yii je akoko iru re ni eyi ti ijoba sim aa pese mokandinlaadofa kaakiri ipinle merindinlogoji ile yii pelu Abuja to je olu ilu Naijiria.

Aare tun ki minister eto ilera, Ojogbon Adewole ati awon iko re ku ise takuntakun ti won n se. O w ape awon gomina kookan nija lati so eto ilera wa ji bi o se ye. Aare ni ijoba apapo ti pese milionu kan ati aabo dola fun ipinle kookan lati rii pe won pese eto ilera to ye fawon obinrin ati omode.

Buhari dupe lowo ijoba ile America, Banki agbaye ati ajo ile Euroopu pelu eka fun idagbsoke agbaye fun iranlowo ti won se lori eto ilera Naijira., banki Sterling, awon ajo to n pese idagbasoke ilera alabode, ati Genetic Electric fun pipese ohun eelo ati oko igbe alaisan ni Kuchingoro.

Minista Eto ilera, Ojogbon Adewole Isaac salaye ipinnu ile ise ijoba apapo lati pese ilana eto ilera kariaye. Ati pe won yoo gbiyanju lati se amojuto to ye si awon ile iwosan naa.

Minista fun Abuja, Ogbeni Musa Bello, naa yombo ipa ti aare buhari n ko lati mojuto eto ilera awon olugbe olu ilu Naijiria ni pato.

 

Fi èsì sílẹ̀