Club Africain fagba-han Rivers United torile-ede Naijiria

Tobi Sangotola

0
107

Iko egbe agba-boolu to n soju orile-ede Naijiria, Rivers United FC, ti ilu Port Harcourt, ti padanu ifesewonse won pelu iko egbe agba-boolu Club Africain torile-ede Tunisia pelu ami ayo meta sookan, ninu ifesewonse boolu akogba idije boolu alafesegba ti awon Adulawo(CAF).
O gba awon iko egbe agba-boolu Tunisia ohun fun iseju metalelogun lati gba ami akoko wole latowo Bilel Ifa, besini ko pe ki saa akoko ifesewonse naa to pari ni Oussama Darragi, ti egbe agba boolu Club Africain torile-ede Tunisia tun gba ami ayo miran wole lati oju boolu agbesile gba.

John Odumegwu, agba-boolu Rivers United lo gba ami ayo kan soso ohun wole ni kete ti saa keji ifesewonse ohun bere, ki Joseph Douhadji agba boolu Rivers United o to gba ami keta wole sinu ile re. Ki saa naa o to pari, Emeka Ogbugh agba boolu fun Rivers United padanu boolu agbesile gba. Ti ifesewonse ohun si pari si ami ayo meta sookan.

 

Tobi

LEAVE A REPLY