Egbe Oselu Alatako ko ipe Aare orile-ede Gabon Fun ijiroro alaafia

Popoola Abiodun ati Tobi Sangotola

0
32

Aare orile-ede Gabon, Ali Bongo, ti gba lati se ipade pelu awon egbe oselu alatako lojuna lati fopin aawo to be sile leyin eto atundi idibo lodun to koja. Awon egbe oselu alatako ko igbese naa.
Lakoko to n fesi si atejade lati ile ise aare, olori egbe oselu alatako, Jean Ping, ri ijiroro naa ti yoo bere ni ojo kejidinlogbon osu keta yii pe oun ko setan lati kopa ninu re.
Jean Ping ti o je alaga ajo isokan ile Afrika (African Union) fesun kan Aare Bongo wi pe eeru ni o fi jawe olubori ninu atundi eto idibo naa. To waye ninu osu kejo odun 2016.
Won tesiwaju wi pe aare Bongo lo awon oloogun lati maa yinbon tu awon afehonuhan ka ni ose to tele eto atundi idibo naa.
Ile ejo ofin lorile-ede naa ko awon esun eeru ati mogumogu eto idibo ti won fi kana are Bongo sugbon awon lameto lagbaye ti benu atelu eto atundi ibo naa .
Ile asofin ile Europe pe abajade eto idibo naa gee bi eyi ti enikeni ko le gbagbo ninu osu keji odunbi otilejepe won ko lati gbe ofin ifiyajeni le orile-ede naa.
Aare Bongo gba ijoba lodun 2009 leyin iku baba re Omar Bongo ti o fi opolopo odun wa lori aleefa.
Orile-ede na ti o je olupese eepo robi lagbaye ,ti o kun fun opolopo alaafia lati igbati o ti gba ominira re lowo orile-ede Faranse lodun 1960.
Bi o tile je pe laasigbo be sile leyin eto idbo naa sibe alaafia ti pada si orile-ede naa.

SHARE

Fi èsì sílẹ̀