Eto inu ifamieye-danilola fawon olorin nile Adulawo ti jade

0
415

Ajo isokan ile Adulawo ti a mo si African Union Commission, (AUC) ti siso loju eegun igbese eto inu fifi ami eye da awon olorin to fakoyo fun gbogbo orisii orin nile Afirika fun todun 2017 nibi eto ti won se nile itura Maslow to wa ni Sandton, lorile ede South Africa.

Aare AFRIMA, Ogbeni Mike Dada, ni igbese akoko ni ki awon eniyan bere iforukosile nipa fifi orin ti won fe fi dije ranse lagbaaye lati ojo Aje ojo kejo osu karun un titi di ojo Aje, ojo ketadinlogun osu keje odun 2017.

Ogbeni Dada ro awon akorin, awon to n mojuto won, awon alafe ati awon elere pelu awon to n ba won gbe rekoodu orin jade lati tete fi orin ti won fe lo fun idije ranse lasiko.

“Ko nii fi se bi olorin naa ba se gbajugbaja to nile Adulawo, kete ti ko ba ti fi orin to fe fi se idije ranse, ko nile ko pa ninu idije nibi eto naa.

Olori eka asa ninu ajo naa, Arabinrin Angela Martins dupe pupo lowo ijoba ile South Africa ati awon eniyan re fungbigba won laaaye lati siso loju eegun eto AFRIMA fun todun yii.

O ni: “A fe gboriyin fun eto AFRIMA nitori ipa pataki to n ko paapaa todun 2014, 2015 ati 2016. opolopo ero lo kopa ninu AFRIMA ni eyi ti awon milionu onkorin lati ekun marun un nile Adulawo ti wa nikale. A dupe lowo AFRIMA fun anfaani lati ri si ilana ofun ekun yii papo, bee naa ni atun n ro eyin to wa nibi lati sa ipa yin kaakiri ile Afirika ki ohun gbogbo le tesiwaju bi o ti ye.

Kin ni AFRIMA ni kukuru                                    

AFRIMA je eto kan to wa fun fifi ami eye dani lola fawon olorin ni eyi ti a gbekale lati pon orin kiko le geg bi ise awon akoni nile Adulawo. O tun wa fun sise afihan asa lorisiirisii ti a ni nile Adulawo ki o je ona ibanisoro pelu awon onkorin kaakiri ekun naa ati lagbaaye ki idagbasoke to ye le de ba ise orin kliko. Eto yii n pese ise fawon oniruuru eniyan kaakiri, o n safihan isese ile Adulawo, o n fon rere awon ohun adayeba ati ohun amusogo ti a ni nile Adulawo lapapo ni eyi to n je ki araye foju rere wo ile Afirika lagbaaye.

Ni ipari, AFRIMA wa fun pipolowo awon orin ile yii atawon onkorin ile Adulawo ni eyi to soo di ipejopo to tobi ju nile Adulawo lapapo ti orisiirisii orile ede si n poungbe lati gbalejo re lodoodun.

Awon to wa nibe

Awon eekan kaakiri lo kopa ninu ipade naa, lara won ni awon asoju ajo isokan ile Adulawo (AU), awon omo egbe igbimo agbaaye fun AFRIMA, awon to ti gba emei eye seyin, awon ti won sese fe dije lati ekun Southern African, awon oniroyin ni ile Southern Africa atawon mii. Awon gbajugbaja olorin mii to wa nibe ni: Wax Dey; Sjava; Buffalo; Mi Casa; Busiswa; The Soil; Heavy K; Ugly Priddy; Cindy Munyavi ati Fungisia.

Awon onise gbigbe orin jade to wa nikale ni Adari Africori Digital Music Solutions, Ogbeni Yoel Kenyan; Adari Content Connect International, Ogbeni Munya Chanesta; Alakoso ekun Africa Sales and Marketing, Sun International, Ms Jennifer Beattie; Adari, Vth Season Management ati Ms Ninel Musson ati awon mii

LEAVE A REPLY