Ezeemo:- Agbelero awon ohun eelo se pataki sidagbasoke oro-aje

0
303

Ogbeni Godwin Ezeemo to je okan lara awon onile ise nla to n ro awon ohun eelo ni Naijiria ti parowa fawon eniyan orile-ede yii lati tubo maa ra awon ohun eelo agbelero ti a se nile funra wa ki a le jo so eto oro-aje Naijiria ji papo.

Ezeemo soro yii nijoba ibile Umuchu Aguata nipinle Anambra pe arowa yii di dandan lasiko yii nitori ina ajoreyin ti oro-aje wa n jo bayii.

Ti won ko ba gbe igbese lati samulo awon ilana ofin ti yoo je ki o rorun lati pese awon ohun eelo agbelero nile, o seese ki o ma bi eso alaafia ni awujo”

Ezeemo ro gbogbo eniyan lati bere si ni ra awon ohun ti a se ni Naijiria funra wa ni eyi to gba pe yoo mu anfaani ba awon eniyan ekun guusu ila oorun Naijiria ti won je olupese awon ohun eelo agbelero julo lorile-ede yii.

O ro awon eniyan lati ra awon ohun eelo agbelero nile wa ki a le begbe pe nitori ko si orile ede to le dagba nipa kiko nnkan wole latile okeere.

 

LEAVE A REPLY