Finland yombo Naijiria lori irogunsinilapa fawon obinrin

0
16
Ayajo ojo awon Obinrin lagbaye

Asoju orile ede Finland ni Naijiria, Abileko Pirjo Suomela-Chowdhury,  gboriyin fun ipa ipese ona irogunsawon obinrin lapa lorisiirisii ti Ijoba Naijiria n se. O soro yii nibi ipade apero ti eka to n mojuto oro obinrin nipinle Eko se agbateru e.

Eto naa waye fun sisami ayajo ojo awon obinrin lagbaye. Suomela ni:”Lati odun meji seyin ti mo ti wa ni Naijiria  ni mo ti kiyesi pe, Naijiria n gbiyanju gidi fawon obinrin won. Orisirisi igbese akoni nijoba apapo n gbe labe Aare Mohamodu Buhari ni eyi to je awokose rere.”

O woye pe, gbogbo obinrin lagbaye lo ni idojuko lorisiirisi ninu esin, isese ati isejoba. O menuba igbese abadofin lorisiirisii ti yoo daabo bo eto awon obinrin lagbaye pelu akori ayajo awon obinrin fun todun yii pe ki obinrin to obinrin ninu ayipada rere.

Komisona fun oro awon obinrin ni ipinle Eko, Abileko Lola Akande ninu oro ikini kaabo re  ro awon obinrin Naijiria lati ji si itaniji pe ko si ohun ti okunrin n se tobinrin ko le se. pe ki onikaluku dide si ipenija lati bo loko eru.

Akande soro lori awon ona ti obinrin le gba lati je obinrin rere loode oko, nibi ise, ninu ile,  nile ijosin ati nibi gbogbo. O ro awon eni kookan ati onile ise nlanla lati faaye gba awon obinrin.

SHARE

Fi èsì sílẹ̀