Garba Shehu ni Is̩é̩ Ààre̩ Buhari kò dínkù rárá

0
15

Ile ise ijoba apapo lÁbuja ti ni iro pata ni aheso to ni ise ti Aare n se ti dinku latigba to ti de lati London lojo kewaa osu keta odun. Malam Garba Shehu to je agbenuso fun Aare, to tun je oludamoran agba lori oro iroyin ni oro abadofin ni Aare Buhari fi gbogbo ose to koja mojuto.
O ni iro ni pe aare ko I tii jade latigba to ti de ati pe wakati meta sim ern lojumo ni Aare fi n sise. Aare buhari nn gbiyanju ipa re lati tubo sise fun awon eniyan Naijiria to nigbagbo ninu re. koda aare ko tii gba ojo kan fun isinmi lati igba to ti de pada.
Garba ni kete ti Aare ti fiwe ranse sawon Asojusofin pe oun ti de lati bere ise pada ni oun ati igbakeji re, Ojogbon Yemi Osinbajo ti n se ipade lorisiirisii lati jabo ibi ise de duro funra won. O ni: “Aare sese gba abo ise to fi sile fun igbakeji re lori ile ejo to ga julo, lori ekun Naija-Delta, eto oro aje paapaa riri eto oro aje wa da pada sipo pelu ipinnu lorisiirisi ni awon to nii se pelu eto ogbin ninu isejoba re.”
Bakan naa ni aare ti se ipade pelu Godwin Emefiele to je gomina banki Naijiria lori ibi ti okowo Naijiria de duro.
Ni afikun, Aare ti se ipade pelu Bukola saraki to je aare ile igbimo asofin naijiria ati Yakubu Dongara to je Agbenuso ile asoju-sofin. O ni lojo ‘Bo ni Aare se ipade pelu Abba Kyari ati Kemi Adeosun, minister fun eto inawo Naijiria pelu awon ti eto ipinnu isuna owo to je Udoma Udo – Udoma.
Aare tun ti pade pelu awon gomina ni eyi ti igbakeji re dari. Lojo Jimo ni aare ria won to nii se pelu eto abo ko to lo si mosalasi lo kirun. Aare n poungbe nkan rere fun Naijiria pelu ife inu lati sa ipa tire lati sin awon eniyan Naijiria.

SHARE

Fi èsì sílẹ̀