Gómìnà ìpínlè̩ Benue yànàná lori às̩e̩ tó pa fáwo̩n Daran-daran

0
15
PIC.5.HERDSMEN AND THEIR COWS ON THE MOVE AT NASARAWA-EGOM ON FRIDAY (10/7/15). 5300/10/7/2015/CH/NAN

Samuel Ortum to je gomina fun ipinle Benue ni Naijiria ti salaye pe, iro pata ni pe oun ni ki awon daran-daran ko kuro nipinle Benue. Orisiirisii iroyin lo ti jade lataari ikolura laarin awon daran-daran ati awon agbe nipinle Benue. Ortom yanana lori koko yii nile ijoba lasiko to n se ijoba pelu awon eekan ninu isejoba re.
Didaabobo awon eniyan ipinle mi

“mo ni ki awon daran-daran ti won n gbebon fi ipinle mi sile . won ko ko eeyan mora rara. Won n pa awon eniyan ipinle mi nigba gbogbo. O soro fun mi lati laju mi sile ki talubo ko woo, ki n ma le pese aabo to peye fawon eniyan ipinle mi. Ise agbe nise aayo awon eniyan ipinle Benue. Ija laarin awon daran-daran ati agbe to ge.”
O ni oun ti seto iforijin fawon to ba jade sita sugbon oun ko ki awon eniyan ipinle Benue funra won gbeja ara won nipa hihu iwa taniomumi. Iwa taniomumi buru ju iwa odaran ole jija ti a n gbogun ti ni Naijiria bayii.
Bakan naa lo ro awon agbe lati dekun gbigbe ibon rin kiri nitoripe oun ti seleri lati daabo bo won bi o ti ye. O ni ko si ile taara fun daran-daran nitoripe gbogbo ile ni won ti fi gbin ohun ogbin tan. O ni ona abayo ni ki ijoba apapo ati ti ipinle fowosowopo lati pese ile jije fun eran osin fawon daran-daran ati eran osin won.

SHARE

Fi èsì sílẹ̀