Gomina ipinle Bauchi yan iko agbemila fun egbe agba-boolu Wikki Tourists

Popoola Abiodun / Tobi Sangotola

0
507

Gomina ipinle Bauchi, Abdullahi Abubakar, ti yan iko agbemila fun egbe agba-boolu Wikki Tourists, lati ran iko naa lowo kuro ni ipo ti won wa lori tabili idije boolu alafesegba orile-ede Naijiria(NPFL).

Iko egbe agba-boolu Wikki Tourists lowa ni ipo mokandinlogun lori tabili, pelu ami mokanlelogun ninu ifesewonse mokandinlogun ti won gba, ti won si padanu ifesewonse meta ninu ifesewonse marun ti won gba seyin.

Awon omo egbe iko naa ni, Auwalu Baba Jada, ti yoo je alamojuto agba fun iko egbe naa, ti alamojuto iko egbe agba-boolu orile-ede Naijiria, Pascal Patrick, yoo sise gege bi olugbani ni moran fun iko egbe naa, awon omo egbe ti o ku ni, Sadiq Yusuf Zaria, Paul Gambar, Umar Ahmed Ilelah ati Abdullahi Ibrahim.

Gege bi awon akoroyin ti so , iko agbemila ohun ni yoo beere ise ni kiakia, ti won yoo si jabo ise won si ile ise Gomina lai fi faale rara.

Gomina Mohammed Abdullahi  so wipe,  “A ti yan iko agbemila fun egbe agba-boolu Wikki Tourists, lati ran won lowo kuro ni ipo ti won wa lori tabili idije boolu afesegba torile-ede Naijiria, pelu awon omo egbe yii,  Auwalu Baba Jada, Pascal Patrick, Sadiq Yusuf Zaria, Paul Gambar, Umar Ahmed Ilelah ati Abdullahi Ibrahim.

Awon iko agbemila naa ni yoo si maa jabo ise won si Gomina latowo Alhaji Maijama’a Mato ti o je okan gboogi lara awon agbani ni moran si Gomina ipinle ohun.

TOBI/ABIODUN

 

LEAVE A REPLY