Gomina Ipinle Kogi Bu Enu-Ate Lu Ikolu Ile-Ijosin Ipinle Anambra

Ronke Osundiya

0
507
Gomina ipinle Kogi, Alhaji Yahaya Bello

Gomina ipinle Kogi, Alhaji Yahaya Bello ti bu-enu-ate lu ikolu awon olujosin ti o waye nile ijosin Catholic kan nipinle Anambra  gege bi eyi “to buru jai, ti ko si je itewogba,’

Nigba ti agbenuso re oga-agba fun eto iroyin ati oro igbodegba, gomina oun  so pe, a gbodo fi awon onise ibi naa jofin, lati le dekun iru isele bayii lojo-iwaju,

O fikun oro re pe“Iru igbese ole-afajo ati alai-lakikan-ju ti awon asekupani yii safiha re nipinle Anambra je ohun to bani-ninu je lopolopo fun orile-ede ati omo-eniyan lapapo.

Yahaya tun so pe,”A gbodo gbara wa kuro lowo ironu ankaribaso, ki a si dide giri lati daabobo emi awon eniyan lowo awon asekupani ika eda.  Mo ba awon ebi oloogbe, awon omo ipinle Anambra, awon omo orile-ede Naijiria ati egbon mi, gomina Willie Obiano kedun gidi-gidi, a maa bori gbogbo isele laabi yii,”

 

Ronke Osundiya

 

LEAVE A REPLY