Ijoba apapo Naijiria f’awon ara ilu lokan bale lori aabo ni Aso Rock

0
15

Mallam Garba to je oludamoran agba fun Aare Buhari lori iroyin ti fawon eniyan lokan bale pe ko si wahala nibugbe Aare Naijiria ti a mo si Aso rock nilu Abuja to je olu ilu Naijiria.
Garba salaye kikun ninu atejade to fi sita fawon oniroyin pe ibon to dun ni Aso rock seesi ni lojo’ru to koja. O ni osise eleto aabo to seesi yinbon naa wa fun iforowanilenuwo ni Aso rock lori isele kan to sele ni. Koda, osise yii kii se fun Aso rock rara. Garba ni gege bi a ti laa kale pe ki won fi ibon won sile ni o fe se nigbati osise eleto aabo yii fe fa ibon re kale ni o seesi yin.
Bakan naa lo safikun pe o seni laanu pe ota ibon yii seesi lo ba eleto aabo naa ati alase to gbe ounje wa ni eyi ti awon dokita si ti toju awon mejeeji bi o ti ye ti won si ti pada sile koowa won.

Fi èsì sílẹ̀