Ijoba ipinle Delta ati aladani kan towobo adehun ogun-milionu dola lori ogbin ope

0
295

Ijoba ipinle Delta ti buwolu iwe adehun pelu ile ise aladani Norsworthy Investment Limited kan lori ise akanse isowo ope ati epo ninu saare ile to to eeka egberun meta.

Agbegbe Akwukwu–Igbo nijoba ibile ariwa Oshimili ni won yoo gbe ibudo ise akanse naa si. Ogbeni Festus Agas ti je akowe agba ipinle ohun lo towobo iwe adehun naa loruko ijoba. Agais soro lori igbiyanju ijoba ipinle Delta lati satileyin to ye fun olokowo nlanla ki eto oro aje ipinle naa le bureke sii pe: “Kete tijoba yi ti dori aleefa ni Gomina Ifeanyin Okowa ti fipinnu re han lori sisatileyin ti o ye fawon onile ise nlnanla kise le po lopo yanturu ki eto oro aje ipinle ohun le tubo goke agba paapaa fun eto ogbin to je opakutele oro aje ipinle naa

O gboriyin fawon alase ile ise Norsworthy Investment fun ipinnu lati tun ipinle naa se pe ipinle Delta yoo satileyin to ye fun won pe: “Ni temi, mo ro pe igbese adehun ti a ni fi buwolu yii dara julo. Mo fe so pe o je ona abayo si ipese ise ati idagbasoke eto oro aje agbegbe yii”.

Bakan naa, Komisona fun igbero ati igbese inu eto oro aje ipinle Delta, Ogbeni Kingsley Emu, naa yombo igbese akoni fifowosi iwe adehun yii to bere losu mejo seyin pe o dara.

“Laipe nile ise yii wa rijoba ipinle Delta pe won nilo saare ile eeka egberun meta lati fi gbin ope ati ipese ohun ogbin mii fun idagbasoke ni eyi tijoba si ba awon eniyan agbegbe Akwukwu-Igbo soro ti won sigba lati fi ile naa sile fun ogbin ohun:

O menuba pataki ise adari ekun naa, Oloye Obi David Azuka, ti o wa nidi riri ile saare naa gba fun ise akanse yii. O ni ile ekun yii lora pupo fun ise agbe ati pe eyi yoo je ki awon onile ise nlanla miran naa wa da ile ise sile nipinle Delta ti won ba n ri aseyori igbese yii.

Saaju ni Omowe Gabriel Ogbechie to je alaga ile ise Norsworthy Investment Limited, ti soro lori ipinnu aseyori tile ise re nilokan pe: “A feran dida ise akanse sile kaakiri nitori pe ile ise nlanla maa n mu idagbasoke to ye ba ilu ni lai yo ipinle Delta sile rara. Mo fe ki Gomina Ifeanyi Okowa fun iran ati ipinnu re lati mu idagbasoke ba ipinle naa ni eyi ti awa ti setan lati sa ipa tiwa bi o ti ye. Gege bi ile ise. A maa koko naa owo to to milionu dola lona ogun sinu ise akanse yii ki a to maa tun fowo kun ise naa bi o ba se n gberu sii, kise le tete bere ni kia. Mo fi n da awon eniyan ipinle yii loju pe didun losan yoo so fun idagbasoke ipinle Delta lataari ise akanse yii ”

Ogbechie, naa tun ni alaga Inoil Nigeria Limited, okan lara ile ise to n se karakata epo robi ni Naijiria ni ohun ogbin pelu ohun ti Eledaa fi jinki wa ni eyi to ye ki a lo bi o ti ye fun igbadun wa gege bii orile-ede.

Awon mii ti won wa nibe ni awon omo igbimo amusese fun ipinle Delta, awon asoju ile ise Norsworthy Investment Limited ati awon asoju agbegbe Akwukwu-Igbo pelu Omowe Ben Iwezu.

 

 

LEAVE A REPLY