Ijoba Naijiria n fe ki awon eniyan tubo nifura lori Ebola

0
237

Ijoba orile-ede Naijiria ti parowa fawon olugbe orile ede yii lati tubo nifura lori oro Ebola. Ojogbon, Adewole Isaac, to je minista fun eto ilera lorile-ede Naijiria lo parowa yii lori ami arun iba lorisiirisii ati ara gbigbona ati lilaagun pupoju. O ni ki onikaluku sora nigbogbo igba lataari riri ti ajo ilera agbaye WHO tun ti ri Ebola ni orile-ede Democratic Republic of Congo.

Bakan naa ni won tun ro awon osise eleto ilera ti enu bode lati ni akiyesi to daju ki won si tete se ifitonileti nipa alaare kankan ti won ba kefin sibi to ye nibudo eto ilera.

Awon ami Ebola to ye ki won kiyesi ni iba, ki o maa re eeyan lati inu wa, ooyi oju kikoni, isan lile, ki eje maa da lara eniyan lati ara abi lati imu, oju, enu ati bee bee lo.”

Minista ro awon eniyan Naijiria lati ma beru nitori pe ibudo to n mojuto itankale arun ati aisan gbogbo n sise takuntakun fun aabo ilera awon eniyan lori arun gbogbo laiyo iba Lassa sile.

Ojogbon Adewole ro awon ipinle kookan lati bere ikede lori ero amohunmaworan, asoromagbesi ati iwe iroyin, pelu ona ayelujara gbogbo. O ni ile ise ijoba to n mojuto ilera tubo ji giri sise won nipa ona akiyesi gbogbo fun ayewo lori arun Ebola.

Ni ipari, Minista ro gbogbo olugbe orile ede yii lati kara mo imototo, ki won maa fowo nigba gbogbo, ki won se ifitonileti to ye lori akiyesi aisan iba ti won ba kefin.

LEAVE A REPLY