Ijoba Naijiria pase ayewo Ebola fawon Ero to n wole

0
330
A health agent controls the temperature of a passenger leaving Liberia at the Roberts International Airport near Monrovia on Agust 27, 2014. Ebola-hit nations met for crisis talks on August 28, 2014 as the death toll topped 1,500 and the World Health Organization warned that the number of cases could exceed 20,000 before the outbreak is stemmed. The United Nations vowed on August 23 to play a "strong role" in helping Liberia and its neighbours fight a deadly outbreak of Ebola in west Africa, which it said could take months to bring it under control. Liberia has been particularly hard hit by the epidemic that has swept relentlessly across the region since March, accounting for almost half of the 1,427 deaths. AFP PHOTO / ZOOM DOSSO (Photo credit should read ZOOM DOSSO/AFP/Getty Images)

Ijoba orile-ede Naijiria ti pase fawon osise eleto ilera lati bere ayewo ni kikun fun gbogbo awon arinrinajo to n wo Naijiria bayii fun arun ebola. Eyi je okan lara igbese akin tijoba n gbe lati rii pe Ebola ko pada wo orile-ede yii mo. Minista fun eto ilera, Ojogbon Isaac Adewole lo pase yii lasiko to m ba awon oniroyin soro nile ijoba l’Abuja leyin ipade awon igbimo amusese eyi ti Adele aare, ojogbon Yemi Osinbajo se alaga fun.

Lodun 2014 ni Ebola koko wo Naijiria lati ara Patrick Sawyer ara Liberia ni eyi to fi tan kale ti o si gba emi awon eniyan kan.

Adewole, salaye pe Adele aare ti pase fawon ile ise eto ilera lati ji giri sise ayewo yii kina esisi ma le jo wa leemeji.

“A mo nipa itankale Ebola to ti bere ni Congo DRC bayii. Eyi tumo si pe isele kan le ran opolopo ero. A nilati ji giri sipenija yii ni Naijiria bayii ki awon eniyan le maa fura. A gbodo gbaradi lawon aala ile wa ki won ma lo ko ebola wole lati ile okeere nipase oju irinna omi, ona ati t’ofurufu ki a le tete da eyi ti awon osise eleto ilera ba fura si mo lasiko. Adele aare ti pase pe ki ise bere gidi lori awon ona abawo orile-ede yii gbogbo. Emi fun ra mi ti sabewo si papako ofurufu ti Nnamdi Azikiwe nilu Abuja lati wo bise ayewo naa se n lo si”.

Minista nijoba ti sagbekale igbimo ebola eyi ti Onisegun oyinbo Basanyi je alaga re. Oun lo saaju iko to lo ran Liberia lowo lasiko ti Ebola n yo won lenu julo.

Bakan naa ni Adewole ni oun ti jabo fun ijoba ibi ti ise de duro lori arun yirunyirun ni apa ibi kan ni Naijiria.

LEAVE A REPLY