Ijoba orile-ede Naijiria tenumo isakoso to fojuhan gbangba si ara ilu

Abiodun Popoola.

0
307
Ogbeni Abubakar Malami

Ijoba orile-ede Naijiria, ti tenumo ipinnu re lati ri wi pe ko ni si iro tabi etan ninu ojuse ijoba gege bi iran ati erongba isejoba Aare Muhammadu Buhari.

Adajo agba lorile-ede Naijiria ati minisita fun eto idajo , Ogbeni Abubakar Malami, si ipo ti ijoba isakoso bayi duro le lori, lakoko ifilole oju opo fun ile ise naa lori ominira fun eto awon eniyan lori iroyin ( FoI), to wa ye ni ilu Abuja ti n se olu ilu orile-ede Naijiria.

Minisita naa so wi pe ,abadofin lori ominira fun iroyin( FoI), bere ni ojo kejidinlogbon osu kaarun odun 2011 je ohun apeere rere ti won fi lele,lati le jeki gbogbo eniyan ni anfaani si awon iroyin ni awon ile-ise aladani ati ti ijoba,eyi to se pataki lopolopo.

Ogbeni Malami, se afikun oro re wi pe, ojuse ile –ise re ni lati ri wi pe abadofin naa di mimulo eyi ti won si ti se iranlowo fun opolopo ile-ise lati gbe iroyin won soju taye.

Beeni, O tenumo wi pe, ijoba ki yo kuna lati mu erongba yi wa si imuse.

 

Abiodun Popoola.

LEAVE A REPLY