Ijoba Orile Ede Naijiria Ti Pinnu Lati Mu Awon To Lowo Nibi Isele Ipaniyan To Waye Nile Ijosin, Ni Ipinle Anambra

Ademola Adepoju.

0
281
Yemi-Osinbajo

Ijoba orile ede Naijiria ti so pe awon yoo wadii isele ipaniyan to waye lowuro, ojo Aiku nile ijosin Ozubulu ni ipinle Anambra to wa ni ila oorun Gusu orile-ede Naijiria ati lati je ki awon odaran naa  jiya labe ofin.

Awon agbebon kan ti won ko mo lo kolu ile ijosin St. Philips Catholic, to wa ni Ozubulu lojo Aiku, ti won si pa opo eniyan nibe.

Ogbeni Laolu Akande, to je oluranlowo agba fun  igbakeji aare orile  ede Naijiria nipa iroyin ati ikede lo so eleyii lojo Aje, pe adele aare  korira  isele naa.

“ojogbon Osinbajo korira isele buruku yii , bee si ni o ba awon idile, ati awon ara ilu ipinle Anambra,ebi ,ijoba ati ore awon  eniyan to padanu emi won ninu  isele  naa kaanu” ninu iwe atejade kan ti Akande gbe sita.

Akande tesiwaju pe,” won ti fi n to  adele aare leti bi awon iwadii se n lo nipa isele buruku to waye nile ijosin St. Philip Catholic ,Ozubulu ni ipinle Anambra nibi ti won ti pa awon olujosin , ti awon kan si farapa yeleyele.

O ni adele aare si n ba gomina ipinle Anambra Willy Obiano , awon olopaa ati ajo eleto aabo soro papo nipa isele naa.

 

Ademola Adepoju.

LEAVE A REPLY