Ijoba yoo sagbekale fafiti ikoni nipa oko ofurufu

0
23

Ijoba Naijiria ni ise ti n lo lowo bayii lati sagbekale ile eko giga fun ikoni nipa ofurufu. Minista abele fun ile ise ijoba apapo yii, Senato Hadi Sirika lo so eyi nibi iforowanilenuwo ni asiko to n sabewo lo si ibudo ikoni nipa oko ofurufu ni Zaria nipinle Kaduna lapa oke oya Naijiria.
O ni fafiti yii yoo yato sibudo ikoni to wa ni Zaria, nitoripe eleyii ni yoo mojuto ise iwadii ati idagbasoke pelu ona ikoni fawon ogaloga lenu ise to niise pelu ofurufu. Ile eko giga yii ni ireti wa pe to baya yoo maa se oko ofurufu awaarawa lorile ede Naijira. o se apeere awon orile ede bii Brazil ati India ti won n se oko ofurufu ti won pe, laipe laijinna , imo ero Naijiria naa yoo faaye gba eyi lawujo wa.
O ran awon oniroyin leti pe UNDP ati ajo awon onise ofurufu ICAO pelu ijoba Naijira lo bere eyi. Saaju oro re ni adari ile eko ijoba naa, Ogagun Samuel Caulcrick ti ni agbekale ile eko yoo je opakutele fun awon eko to nii se pelu ofurufu ati oko ofurufu.
Bakan naa lo ki Aare Buhari fun ise takuntakun to n se lati so ile eko naa di okan gboogi nile Afirika.

Fi èsì sílẹ̀