Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ìpínlẹ̀ Èkó fọwọ́ sí Àbádofin Tó fòfin de Ìwà Ìmúninígbèkùn ní Ìpínlẹ̀ náà.

0
33

Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ìpínlẹ̀ Èkó fọwọ́ sí Àbádofin Tó fòfin de Ìwà Ìmúninígbèkùn ní Ìpínlẹ̀ náà.
Ile igbimọ Aṣòfin Ipinlẹ Eko ti fọwọ́ sí abadofin to de iwa imuninigbekun. Abadofin naa ti gbogbo ile dibo fọwọ si naa ni o ṣafihan ijiya iku fun ẹnikẹni to ba fipa mu eniyan ni igbekun, ti ẹni bẹẹ si ku si i lọwọ. Bi ẹni bẹẹ ko ba si ku, amuninigbekun naa yoo lọ si ẹwon ‘gbere.
Ile Igbimọ naa sọ abadofin yii di ofin lẹyin ti Alaga Igbimọ to n ri si Ọrọ Idajọ, Ifẹhonu-han, Ẹtọ Ọmọniyan ati Ajọ Eleto Idibo, ẹka ti Ipinlẹ Eko, Aṣofin Adefunmilayọ Tẹjuoṣo ka ijabọ abajade abadofin naa fun Ile.
Abadofin yii ni ireti wa pe yoo fopin si ọrọ imuninigbekun ni Ipinlẹ Eko. Eleyii ti wọn sọ dofin, lẹyin ti wọn ka a ni igba kẹta gẹgẹ bi eto Ile.
Agbẹnusọ Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko, Aṣofin Mudaṣiru Ajayii Ọbasa, ti o ka ipele ogun inu abadofin naa lo ṣe agbatẹru gbigba ofin naa wọle pẹlu ohun ẹnu awọn aṣofin to ku.
Lẹyin eyi ni Agbẹnusọ Ile paṣẹ pe ki Adele Akọwe-agba Ile, Ogbẹni Azeez Sanni fi ẹda abadofin ti wọn fọwọ si naa ṣọwọ si Gomina Ipinlẹ Eko, Ọgbẹni Akinwumi Ambọde lati fọwọ si i, ki o le di ofin ilu.
Ofin naa fi mulẹ pe ẹnikẹni to ba mu ẹnikan ni igbekun fun idi kan tabi omiran, to wa n beere fun iye owo kan lati fi onitọun silẹ, idajọ iku ni wọn yoo da fun amuninigbekun naa bi ọwọ ba tẹ ẹ.
Bakan naa , ẹnikẹni to ba purọ tabi ṣe

954429_5
Agbenuso IlE iGBIMO ASOFIN IPINLE EKO

ke pẹlu ọrọ to nii ṣe pẹlu iwa imuninigbekun, yoo fi ẹwọn ọdun meje gbara. Bẹẹ ni, ẹnikẹni to ba n halẹ lati mu ẹnikan ni igbekun, boya nipa lilo ẹrọ ibanisọrọ, tabi ọna miiran lati dunkooko mọ onitọun, yoo lọ si ẹwọn ọdun mẹẹdọgbọn bi ọwọ ijọba ba ba a.
Bakan naa ẹwọn ọdun mẹrinla ni ti onile tabi oni nnkan ti wọn lo lati fi mu eniyan nigbekun, to si mọọmọ gba iru iwa bẹẹ laaye.
Aṣofin Nurudeen Saka-Ṣolaja ti o n ṣoju ẹkun Ikorodu Keji ninu Ile naa sọ pe abadofin yii yoo ṣadinku iwa imuninigbekun ni ipinlẹ Eko, eyi to jẹ aṣa tuntun bayii ni ipinlẹ Eko. O ni: “Aṣa rere ni a mọ awọn ọmọ ipinlẹ Eko mọ; iru eyi ṣajoji siwa lọpọlọpọ. Pẹlu abadofin yii, yoo ṣe adinku jọjọ si iwa mimu eniyan ni igbekun . Yoo si tun jẹ arikọṣe fun awọn ipinlẹ miiran lorilẹ-ede Naijiria”

Fi èsì sílẹ̀