Ile-Igbimo Asofin fe ki won jara-mose akanse oko oju-irin ilu Eko si Ibadan

Ronke Osundiya,

0
301
IIle-igbimo asofin orile-ede Naijiria ti pe fun jijara-mose akanse oju-irin igbalode

Ile-igbimo asofin orile-ede Naijiria ti pe fun jijara-mose akanse oju-irin igbalode  ni opopona marose ilu Eko si Ibadan, lati le ba akoko ti won da fun lilo re ni odun 2018.

Awon alaga igbimo ti o n ri si oro igbese abele ati ti ile-okere, Shehu Sani ati irinna-oko oju-popo Gbenga Ashafa, ni o pe ipe yii lasiko abewo ati igbele won ise-akanse ipinle Eko naa.

Asofin Shehu Sani fi erongba igbimo iko mejeeji naa han pe, idunnu nla ni yoo je fun ile-igbimo asofin elekejo lati ni aseyori lori ise-akanse oko oju-irin naa

O se lalaye pe, erongba ise-akanse oko oju-irin ohun ni lati le mu igberu ba eto oro-aje orile-ede Naijiria ati lati pese ise fun awon odo langba lawujo.

Sise amulo ise-akanse:

Gege bi oro re, nigba ti ile-igbimo asofin n fowo si erongba ise-akanse oko oju-irin naa, o kanpa fun igbimo ti oro naa kan lati foju si sise amulo owo ti orile-ede Naijiria ya naa..

 “Asofin Shehu Sani salaye pe, o ri aridaju to han gbangba-gbangba pe, gbogbo owo ti ijoba orile-ede Naijiria ya lati  lo fun awon omo-orile-ede Naijiria ni won yoo se amulo re, bi o ti to ati bi o ti ye. Ni bayii abewo yii je igbese akoko fun aseyori erongba ati igbekele ti a je awon omo orile-edenaijiria.”

Asofin Shehu  so pe, ti won ba ti n se amulo owo ti won n ya  nipele ijoba apapo ati ti ipnle lateyin wa, ti won si se amoju ati amulo re lona ti o dara, o daju pe, Orile-ede Naijiria yoo ti dara ju bi o ti way ii lo lona mewaa.

Asofin Ashafa so wi pe, sise  ayewo yii, ni lati satileyin fun igbimo ti o n ri si irinna oko loju-popo lati se amulo erongba ise-akanse ti won fowo si naa,eyi ti o je ki ijoba orile-ede Naijiria le bere fun eyawo nile ifowo-pamo Exim lorile-ede China.

Asofin Ashafa so pe, ojuse ile-igbimo ni lati ri daju pe, ko si kolofin ninu bi won se ina owo ara-ilu naa.

Owo ti won fowosi:

O se lalaye pe, ajosepo ise igbimo ohun dale awon agbegbe to kan, ile-ise eto irina-oko ati awon ti oro kan, lati pin owo ti won ya naa, eyi ti iye re n lo bi bilonu mefa owo dola.

Gege bi oro re,” owo ti won ya naa ni won yoo lo fun sise irina oko oju-irin lati ilu Eko si Ilu Kano, lati ilu Kani de Kaduna, , ilu Eko de Ibadan ati Ilu Calabar.

 “Ireti wa wi pe, awon agbase-se ise-akanse ohun ti a mo si (China Civic Engineering Construction Corporation) (CCECC) yoo tele akoko ti fenuko le lori lati pari ise naa, fun anfaani awon omo orile-ede Naijiria.

Oga-agba ile-ise agbasese naa LeoYin gboriyin fun ile-ise to n ri si isuna-owo fun ifowosowopo pelu ile-ifowo-pamo Exim ti orile-ede China, eyi ti o sokufa ise-akanse yii, ati anfaani ti awon omo orile-ede Naijiria yoo ni ti ise ohun ba pari.

Ogbeni Yin so pe, aroroda ojo ati agbara abe ile lo sokunfa ifaseyin ise-akanse naa.

Asofin Gbenga Ashafa ati Shehu Sani  so lasiko abewo si ibi ise-akanse naa, fi da awon omo orile-ede Naijiria loju pe, ile-ise CCECC  ko ni ja won kule ninu sise ojuse re, lati le je ki ise naa pari lasiko ti won fenu ko le lori.

 

Ronke Osundiya,

LEAVE A REPLY