Ile-igbimo asofin yoo mu atunto ba ofin to ro-mo idagbaseke enu-ibode

Ronke Osundiya.

0
254
Ile-igbimo asofin orile-ede Naijiria

Ile-igbimo asofin orile-ede Naijiria ti bere atunse si ofin ti o ro mo ile-ise to n ri si idagbasoke enu-ibode, eyi waye lati le gbogun ti awon ipenija ti awon ilu ti o wa ni enu-ibode n koju

Alaga igbimo to ri si oro ipinle ati ibile nile igbimo asofin agba, asofin Abdullahi Gumel ni o soro yii di mimo ni ilu Abuja lojo-Ru(Wednesday),

O  fikun oro re  pe,” ofin yii yoo faye gba ile-ise ohun lati wa iyanju si awon ipenija ti o ba waye ni awon agbegbe enu-ibode.

O selaye pe, aikobi-ara si igbese yii n se akoba fun awon olugbe enu-ibode, ni eyi ti o so pe, ile-igbimo asofin elekejo ti pinnu lati gbe igbese ti o ye lori oro naa.

O se lalaye pe, lara awon atunto ohun ni lati wa woroko fi sada lori awon ilu miiran ti won wa ni enu-ibode, amo ti won ko si labe ofin ohun.

 “A ni awon ipinle meji-lelogun ti won wa ni enu-ibode, ni eyi ti awon die wa ni eti okun, nigba ti awon enu-ibode miiran fara ti awon orile-ede miiran”.

“Yato si awon wonyii, a tun ni awon miiran ti won ko yo rara ninu ilana ofin naa.

“Eyi je okan lara idi ti a fi n se atunto ilana ofin ti o se agbekale ile-ise ti o n ri si idagbasoke enu-ibode, lati le ko awon ilu yoku sabe ofin naa.

“Bi o se wa ri bayii, ilu ti o ba wa ni bi iwon bata marundinlogun si enu-ibode, amo ninu atunto yii a o so di iwon bata marundinlogbon, lati le faye gba awon ilu pupo mora, ni eyi ti abadofin ohun ti gba ipele akoko koja’.

Asofin Gumel so pe, bi o tile je pe, igbimo alamoju-to kan ti wa ni sepe; eyi ti igbese won je ipenija kan gboogi lati je ki ile-ise ohun se ojuse won bi o ti to ati bi o se ye.

Gege bi oro alaga igbimo ile-igbimo asofin ohun, igbimo alamojuto naa ti yan igbakeji aare gege bi alaga won, ti awon minisita si je apapo omo-egbe igbimo ohun.

O salaye pe, owo igbakeji aare ati awon minisita kun fun ise lopolopo, eyi ti o fa idiwo die lati se ojuse won gege bi alamojuto ile-ise naa, toripe owo won ku pupo fun ise.

 “Pelu atunto yii, a o ni awon omo-egbe igbimo metala, eyi ti yoo je apapo alaga ati awon omo egbe mekija

O se lalaye pe, awon omo egbe meji-meji yoo wa lati ekun mefa, ni eyi ti aare funra re yoo yan alaga lati le se ipade lori ona ti won yoo gba fi satileyin fun iko ohun..

Lori isoro aisi atileyin owo fun ile-ise naa lateyin wa, asofin Gumel so pe, pelu atileyin igbimo yii, eto isuna odun 2017 yii gbe peeli soke.

Bakan-naa ni o so pe, ki oun to di alaga igbimo ti o ri si oro enu-ibode yii, isuna owo ile-ise ohun kere lopolopo, eyi ti ko le mu ayipada kankan ba awon ilu enu-ibode, “o fi mule pe, igbimo naa yoo se amojuto gbogbo owo ti ijoba ba fun ile-ise naa fun awon ise-akanse gbogbo”.

 

Ronke Osundiya.

LEAVE A REPLY