Ile ise ijoba apapo fun eto ilera yoo seto to ye lati fopin si iko-ife

0
9576
Nigeria's Minister of Health Isaac Folorunso Adewole attends an emergency National Council on Health meeting on the control of Lassa Fever in Abuja, Nigeria January 19, 2016. REUTERS/Afolabi Sotunde - RTX231AG

Minista fun eto ilera, Ojogbon Isaac Adewole ti ni igbese ti n lo lowo lati sagbekale awon ilana apapo lati fopin si iko-ife ni Naijiria ati itoju re.

Minista naa soro yii lasiko to n si awon ohun eelo fun lilo nibudo ayewo ati awon ohun eelo ise abe ni ile iwosan ijoba apapo ti fafiti Ibadan ni UCH. O ni Naijiria ni agbaye ka si orile-ede kerin ti arun iko-ife n ba finra julo lagbaye ni eyi to bi ipinnu ijoba lati wa ojutu sii.

Ojogbon Adewole fidunnu re han sile ise Agbami Co-ventures pe: Pupo ninu awon orile-ede ti won ba gbaju mo eto ilera ni won maa n saseyori ninu eto oro aje won, bii Malaysia, Thailand, atawon miran. Eyi fihan pe mimojuto eto ilera wa dise fun gbogbo wa”

Minista tun si awon ohun eelo iko-ife ni ile iwosan tijoba ti won pe ni Government Chest Hospital, to wa ni Jericho nibadan. O ro awon toro kan lati sise papo pelu ijoba apapo lati ri aridaju pe won n sise ayewo bo ti ye nitori o si to ida ogorin ninu ogorun un aisan iko-ife ti won ko tii mo nitori ko si ayewo fun un. O ni kijoba to le saseyori lati gbogun ti iko-ife patapata, a gbodo sise papo pelu awon aladani, olutoju alaisan, awon apoogun atawon olori elesin kookan atolori agbegbe kookan ki won le tete maa safihan enikeni ti won ba fura si po niko–ife fun itoju to ye.

Ojogbon Temitope Alonge to je oludari ile iwosan ijoba UCH ni ibudo ayewo yii ni eyo kan soso to wa ni ekun guusu iwo oorun Naijiria to ni ohun eelo lati sayewo fun awon oogun ti ko gbo iko-ife. Eto naa waye pelu ajosepo ile ise Star Deep Water Petroleum pelu Agbami field ti Famfa Oil, NAPIMS, NAPIMS, Petroleo Brasileiro Nig Ltd ati ile ise Statoil Night.

 

LEAVE A REPLY