Ile-Ise Oloogun Orile-Ede Naijiria Ti Gba Awon Omo-Ogun Olote Ti Won Le Ni Metala Mora Ni Ipinle Borno

Ronke Osundiya

0
355
Ile-Ise Oloogun Orile-Ede Naijiria

Iko omo-ogun orile-ede Naijiria ti won n sise akanse alaafia kan-n-pa ti gba awon omo-ogun olote metala  kaakiri awon agbegbe nipinle Borno ati ipinle Adamawa mora lasiko ise-akanse alaafia won..

Agbenuso fun ile-ise oloogun, ogagun-agba Sani Usman ni o soro yii di mimo ninu atejade kan, eyi ti o so pe, won ri awon mejila ko lasiko ti awon omo-ogun ohun fara pamo sibi ikorita-meta Miyanti-Banki nipinle Borno nigba ti won ri okan yoku ni agbegbe Kafin Hausa ni ijoba ibile Madagi nipinle Adamawa.

Ogagun Usman fi kun-un oro re pe,” ni ojuna Dukje-Mada leba abule Gulunmba Gana ni awon omo-ogun ti ri pupo awon omo-ogun olote naa ko.

 “ O wa se ni laanu pe, awon omo-ogun meji ni won padanu-emi won nigba ti oko ti won wa ninu re te nnkan oloro ti won ri mole si eba oju-ona, ti awon merin miiran si farapa yanna-yanna.”

O salaye pe, awon akinkanju oloogun ti won kagbako isele yii ati awon ti won fara pa ni won ti gbe lo si ilu Maiduguri.

O daruko awon eroja ti won gba lowo awon odaran naa bi: Okada mejidinlogun, ogbon apo iyefun, abo epa kan, apo iyo meji, apere obi meji, ero iriran marun, awon ohun mimu elerin-dodo ati awon aso odindi merin.

Gege bi oro re, awon nnkan miiran ti won tun ri gba ni: apo ora sweeti meji, apo ose ifoso kan, apo maagi meji, bata iwe meji,abbl.

Bakan-naa ni o daruko owu iranso, galonu ogun herbicide merin, galonu ororo an, apo ata kan, ati egberun merin Naira.

Ogagun Usman tun so pe, awon oko oloogun ohun tun gba sinlinda mesan-an, ibi ipese ohun oloro, ni eyi ti won si ba ibe je,  ibon AK-47 ti numba re je 02527 MTD ati iwe royin kan.

 

Ronke Osundiya

LEAVE A REPLY