Ile riri pa awon metala, márùndínlọ́gọ́sàn án eniyan si farapa lorile ede china

Ademola Adepoju.

0
170
Ile riri pa awon metala, márùndínlọ́gọ́sàn án eniyan si farapa

Awon eniyan metala pelu awon arinrinajo mefa ni won gbemi mi , ti awon eniyan bi i márùndínlọ́gọ́sàn si farapa  nibi  ti isele ile riri ti  kolu agbegbe kan lapa oke Gusu  Sichuan lorile ede  China. Awon osise ijoba ati oniroyin orile ede China  lo so eleyii lojoru.

Isele ile riri yii waye nigba to kolu agbegbe kan lapa oke  Guangyuan lojo isegun. Omo orile ede Amerika to n sise iwadii  nipa ohun  alumooni ile , lo so eleyii.

Ile riri yii koko bere ni owuro ojoru lapa oke Xinjiang, bo tile je pe ko si eni to farapa nibi isele naa gege bi osise orile ede China se so.

Ijoba Sichuan ti so pe awon eniyan bii ogorun un lo ti ri sinu ile, leyin isele ile riri yii. Awon mefa ni arinrinajo ti o gbemi mi , gege bi osise ijoba orile ede China se so.

Akoroyin fun ijoba ipinle Xinhua so pe, awon eniyan  metala lo gbemi mi. Amosa, awon arinrinajo to le ni egberun lona ogbon  ni ijoba orile ede naa ti ko kuro nibi ti isele naa gbe sele.

 

Ademola Adepoju.

LEAVE A REPLY