Ile South Sudan safikun owo igbase fawon osise lati ile okeere

0
19
Ile South Sudan

Ile South Sudan ti safikun owo iwe igbase lati sise nile naa ni ida ogorun un fawon eniyan ile okeere to n gbe orile ede naa lainifise ogbele to m ba orile ede naa finra lowolowo.

Ile South Sudan ni orile ede to sese gba ominira julo lagbaye, won si ti bere ogun abele lati odun 2013 nigba ti Aare Salva Kirr jawe lo gbele e fun igbakeji re, Riek Machar lataari aigbora eni ye to sele laarin won

losu to koja ni ajo agbaye fihan pe orile ede naa n ba ogbele finra gidigidi, akoko iru re laarin odun mefa won. iwadii fihan pe o to idaji awon ara ilu to to milionu marun un abo ni ebi yoo maa pa titi osu keje odun.

Pelu gbogbo isoro yii ni Juba tun so owo igbase fun ise akosemose di owo dola egberun mewaa fawon osise lati ile okeere nigba ti awon osise ti ko kosemose yoo ma san egberun meji owo dola, ti awon osise lasan yoo maa san egberun kan owo dola bere lati ojo kini osu keta odun yii.

Edmund Yakani to je oludari ile ise irogunsinilapa ti ki se tijoba ni igbese yii yoo din odinwon awon osise ile okeere ku ni orile ede naa. o le ni milionu meta awon eniyan ile naa ni ija yii ti je ki won kuro nilu naa si lo sibomiran.

SHARE

Fi èsì sílẹ̀