Ipinle mewaa ni yoo kopa ninu idije ere-idaraya boolu afigi-gba

Tobi Sangotola

0
339

O kere tan, ipinle mewaa ni yoo kopa ninu idije ere idaraya boolu afigi-gba (Hockey National League), ni papa isere Abuja, bere lati ojo Aje to n bo.

Akowe agba egbe naa, Iya afin Rita Akande, lo so eyi di mi mo, to si ni idije ohun ni yoo pari logunjo osu karun un odun yii.

Rita tesiwaju, pe iko egbe to ba se daradara yoo pegede sinu idije to gbayi julo torile-ede Naijiria.

O daruko ipinle Delta, Edo,Bauchi ati Nasarawa lara awon ipinle ti yoo kopa ninu idije to n bo lona ohun,

Akowe agba naa tun ni, iko orisii meta ti won je kiki obinrin naa yoo kopa ninu idije ohun.

LEAVE A REPLY