Ipinle Taraba fe safihan ohun alumooni re ni Germany

0
117

Awon omo igbimo ati alamojuto eka iwakusa ipinle Taraba ti yan Gomina Darius Isiaku to n tuko ipinle Taraba lati lo safihan awon alumooni ile tipinle naa ni ni ile Europu. Eto naa yoo waye ni Frankfurt ni orile-ede Germany lojo kejila osu kefa si ojo kerinla osu naa.

Lara awon ohun alumooni tipinle Taraba ni ni goolu, okuta olowo iyebiye lorisiirisii bii:  zinc ore, topaz, sapphire, futile, quartz, graphite, beryle ati awon mii. Ogbeni Saturday Jackson, to je alamojuto apero naa to je akosemose lori imo awon okuta olowo iyebiye ati onisowo ni pasipaaro ni Nigeria ati Germany.

Ogbeni Saturday Jackson ninu atejade to fi sita ni won yan gomina ipinle naa lati lo safihan awon ohun alumooni ile ki awon to nife si karakata awon ohun alumooni le dowopo pelu ipinle Taraba.

Apero yii yoo je kijoba Taraba ni anfaani lati ri awon olokowo ile okeere to nife si ohun alumooni ni aladani ati tonile ise nlanla wa si Taraba.”

O ni apero olojo meta naa yoo da lori imo ero ni kikun, ohun gbogbo to nii se pelu iwakusa atawon ohun alumooni. Odoodun ni eto naa n waye ni eyi ti awon olukopa n ko eko sii lori anikun imo. Ireti wa pe awon iko ijoba to n lo ati awon awakusa yoo ni anfaani lati bere ajosepo fun idagbasoke ninu iwakusa.

LEAVE A REPLY